Àtúngbéyẹ̀wò Ìlò Àti Ìṣesí Àwọn Ọ̀rọ À-So-Ọ̀rọ̀-Pọ̀ Ní Èdè Yorùbá
Main Article Content
Abstract
Ninú gírámà èdè Yorùbá, àwọn onímọ̀ gírámà ṣe àkíyèsí pé àwọn ọ̀wọ́ ọ̀rọ̀ kan wà tí wọ́n máa ń lò láti fi so ọ̀rọ̀, àpólà tàbí gbólóhùn méjì pọ̀. Ẹnu kò lórí ọ̀rọ̀-àsopọ̀ ti ẹyọ ọ̀rọ̀ àti àpólà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀wọ́ àwọn onímọ̀ kan náà tilẹ̀ sọ pé kò sí ohun tí a lè pè ní ọ̀rọ̀ àsopọ̀ tí ó ń so gbólòhùn pọ̀, àwọn onímọ̀ mìíràn sì gbà pé ó wà. Ohun tí a fẹ́ tẹpẹlẹmọ́ náà ni láti ṣàgbéyẹ̀wò ìlò ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọ̀rọ̀-àsopọ̀ wọ̀nyí, kí a mọ iye wọn, àti àwọn òté tó de ìlò wọn nínú èdè Yorùbá. A ṣe àkójọ àwọn détà lóríṣìíríṣìí láti inú àwọn onírúurú ìwé ti wọ́n kọ lédè Yorùbá àti ọ̀rọ̀ ẹnu àṣàyàn àwọn tí ń sọ èdè Yorùbá. A kò ṣàmúlò tíọ̀rì kankan nínú iṣẹ́ yìí kí a lè walẹ̀ jìn lórí àpèjúwe ìṣesí àtì ìhùwàsí àwọn ọ̀rọ̀-àsopọ̀ wọ̀nyí. Ohun tí a ṣe ni pé, a ṣàpèjúwe ìlò àti ìṣesí àwọn ọ̀rọ̀-àsopọ̀ ni. A rí i pé ọ̀rọ̀-àsopọ̀ Yorùbá wà ní abẹ́ ìsọ̀rí wúnrẹ̀n aṣegírámà nítorí àwọn àbùdá ìsọ̀rí náà tó pinminrin sínú rẹ̀. Bí a bá gùnlé ìlò àti ìṣesí wọn, a lè pín ìsọ̀rí ọ̀rọ̀-àsopọ̀ Yorùbá sí ọ̀wọ́ méjì gbòòrò: àkọ́kọ́ ni ọ̀rọ̀-àsopọ̀ tí ó pín sí i: ọ̀rọ̀ a-so-ọ̀rọ̀/àpólà-pọ̀ àti ọ̀rọ̀ a-so-gbólóhùn-pọ̀. Èkejì ni ọ̀rọ̀-a-so-èjì-èrò-pọ̀ tàbí ọ̀rọ̀-asojú-sòdì-pọ̀/elérò ajárètí, ìsọ̀rí yìí náà pín sí: alábala méjì àti aláwẹ́ kan.
Downloads
Article Details

This work is licensed under a Creative Commons Attribution-NonCommercial-ShareAlike 4.0 International License.